Jump to content

Victoria Davies Randle

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Omoba
Victoria Davies Randle
Victoria Davies Randle with her two children, taken in a studio in London in 1901
Ọjọ́ìbíVictoria Matilda Davies
1863
Lagos Colony
AláìsíÀdàkọ:Death date and age text
Lagos
Orúkọ mírànVictoria Davies
Iṣẹ́Socialite
Gbajúmọ̀ fúnBeing the goddaughter of Queen Victoria
Olólùfẹ́
John Randle (m. 1890)
Àwọn ọmọ2
Parent(s)James Pinson Labulo Davies
Sarah Forbes Bonetta
Àwọn olùbátanBabatunde Kwaku Adadevoh
Ameyo Adadevoh

Victoria Matilda Davies Randle ( née Davies ; 1863 – 1920) jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ alájọṣepọ̀ ní agbègbè Victorian ní Ìpínlẹ̀ Èkó.

Àwọn òbí Victoria Davies, Sarah Forbes Bonetta àti James Pinson Labulo Davies, ní ọdún 1862.

Victoria Davies ni ọmọ akọbi James Pinson Labulo Davies, oníṣòwò ọlọ́rọ̀ kan ní ìlú Eko, àti Sarah Forbes Bonetta, ọmọ Egbado omoba kan tí wọ́n ti gbà gẹ́gẹ́ bí ọmọ Ayaba Victoria . Nígbà tí wọ́n bí i ní ọdún 1863, wọ́n sọ ọ́ ní orúkọ Ayaba náà, ẹni tí ó gbà láti jẹ́ ìyá ìyá rẹ̀ pẹ̀lú.

Ayaba fún un ní owó táàkúradó àti ipẹlẹ ọrùn kírístì aláwò wúrà, lẹ́yìn náà ó pe Victoria kékeré wa sí Windsor. Ó kẹ́kọ̀ọ́ ní Cheltenham Ladies' College, [1] àti gẹ́gẹ́ bí ìyá rẹ̀, ó tún fi òye ọgbọ́n tó ga hàn. Ní ọdún 1890, Victoria fẹ́ Dókítà John Randle, dókítà oníṣègùn kan ara ilè ìwọ̀ oòrùn Áfíríkà tí ó kó ẹ̀kọ́ ni Scotland, ti igba àlejò - títí kan gómìnà Lagos Colony - sì wà sibi ìgbéyàwó ní Ṣọ́ọ̀ṣì St. Paul ní Èkó. Reverend James Johnson ló ṣe ìsìn náà, aṣọ ìgbéyàwó rẹ̀ sì jẹ́ èyí ti ayaba, ati ìyá rẹ̀ ti ṣe ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn. [2]

Lẹ́yìn náà, Victoria Davies Randle mú àwọn ọmọ rẹ̀ Beatrice àti John lọ kí ìyá ìsàlè rẹ̀ ní ọdún 1900, ti Bishop Johnson sì sìn lọ sí ibe. Gẹ́gẹ́ bí àṣà àti ìṣe won Ọmọbìnrin Beatrice padà di ìyá isale ọmọbìnrin rẹ̀.

Ìgbéyàwó rẹ̀ túká nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín; ó gbé ní ìdálè pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ, àkọ́kọ́ ní United Kingdom, leyin na ní Sierra Leone, ó padà sí Ipinle ẹ̀kọ́ ní ọdún 1917. Ní London, Davies Randle ti mọ Samuel Coleridge-Taylor, ẹni tí yíò padà jẹ́ olórin aláwò dúdú ará Britain tí ó gbajúmọ̀. Nígbà tí ó yá, Coleridge-Taylor mẹ́nu kàn án gẹ́gẹ́ bí orísun orin àwọn ènìyàn Yorùbá nínú àkójọ orin rẹ̀, Oloba yale mi . Davies Randle fún Coleridge-Taylor ní àkọlé ìlù Yorùbá kan tí ó lò nínú orin Twenty-four Negro Melodies rẹ̀. [3] Àwọn ọdún ìkẹyìn rẹ̀ ni a yà sọ́tọ̀ fún àwọn ìgbòkègbodò Ladies' Club, àwùjọ àwọn obìnrin onípò gíga ní Ìpínlẹ̀ Èkó. [2]

Ó kú ní ọdún 1920. Àwọn ọmọ rẹ̀ tí kì í ṣe pé òun ló bí wọ́n di olùdarí ètò ẹ̀kọ́ ní Nàìjíríà-Ghana Babatunde Kwaku Adadevoh àti ọmọbìnrin rẹ̀, tó je dókítà ni Nàìjíríà àti akọni orílẹ̀-èdè Ameyo Adadevoh .

  • Àwọn ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì aláwọ̀ dúdú, ẹgbẹ́ tí Davies Randle jẹ́ ti
  • Àwọn ọlọ́lá orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, kíláàsì tí ìyá Davies Randle jẹ́
  • Àwọn ọlọ́rọ̀ Nàìjíríà, kíláàsì tí baba Davies Randle jẹ́

Àwọn ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]